1 Chronicles 1:43-53

Àwọn alákòóso Edomu

43Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu, kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:
Bela ọmọ Beori, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.
44Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
45Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
46Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.
47Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
48Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀
49Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani, ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
50Nígbà tí Baali-Hanani kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau; orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. 51Hadadi sì kú pẹ̀lú.

Àwọn baálẹ̀ Edomu ni:
baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti
52baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni. 53baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari,
Copyright information for YorBMYO